Uncategorized

ÀGBÉYẸ̀WÒ FÍÌMÙ “ṢAWOROIDẸ” TÍ Ọ̀GBẸ́NI TUNDE KELANI GBÉ JÁDE

Akẹ́kọ̀ọ́ wa lédè Yorùbá, arábìnrin Ronke Macaulay ni wọn ṣe àgbéyẹ̀wò fíìmù yìí, ẹ wo ohun tí wọn kọ nípa fíìmù náà.

ÀGBÉYẸ̀WÒ FÍÌMÙ ṢAWOROIDẸ LÁTI ỌWỌ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ ÈDÈ YORÙBÁ “RÓNKẸ́ MACAULAY”

“Ìbéèrè àkọ́kọ́ tí ó yẹ kí a ṣe ni wí pé; “Kí ni ìtumọ̀ Ṣaworoidẹ?”

Fíìmù Ṣaworoidẹ láti ọwọ́ Ọ̀gbẹ́ni Tunde Kelani

“Ìbéèrè àkọ́kọ́ tí ó yẹ kí a ṣe ni wí pé; “Kí ni ìtumọ̀ Ṣaworoidẹ?”.

Òun ni gángan àtijọ́ tí ó ṣe pàtàkì nínú ètò ìṣèlú ní ìlú Jogbo tí ó ń bẹ ní ilẹ̀ Yorùbá.Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn ni wí pé ẹni tí bá jọba Oníjogbo láìṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀, lílù ìlù Ṣaworoidẹ yóò fa ikú òjijì fún un.

Ìtàn náà bẹ̀rẹ̀ láti orí Lápitẹ́ tí ó fẹ́ jọba ní túláàsì. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó ti fihàn wí pé ẹ̀dá kan tí ó ní inú búburú àti ìwà ojúkòkòrò ni. Bí wọ́n ṣe kìlọ̀ fún un wí pé ‘ẹni tí ó bá fẹ́ jayé, kí ó má jẹ Oníjogbo’ ni ó ṣe kọ̀ láti ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀.Owó ni ó ń tì í láti ṣe gbogbo nǹkan, títí tí ó fi pa àwọn tí ó ń bá a figa gbága. Ẹnikẹ́ni tí ó bá takòó ni Kábíyèsí Lápitẹ́ máa ń sọ di ẹlẹ́wọ̀n tàbí ẹni àná.

Ní báyìí, àwọn ará ìlú Jogbo jìyà púpọ̀. Àwọn agégẹdú tí wọ́n wá láti ìlú mìíràn pàdí àpò pọ̀ pẹ̀lú ọba Lápitẹ́ àti àwọn Baálẹ̀ láti rẹ́ àwọn onílùú jẹ. Àfáà ń sanra, ìjọ ń rù lọ̀rọ̀ náà. Síbẹ̀-síbẹ̀, Ọba Lápitẹ́ ń ṣe ìlú bó ṣe wù ú, ó sì ń ta ìwọ̀sí bá ẹnikẹ́ni láìwojú. Wọ́n ní ‘ajá tó bá máa sọnù, kì í gbọ́ fèrè ọde’.

Ọ̀gbẹ́ni Túndé Kèlání ṣe iṣẹ́ ńlá sínú fíìmù yìí. Gbogbo àwọn àṣà, oríṣiríṣi ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n gbé yọ. Orin kíkọ, ijó, ìlù, ìtàn sísọ àti aṣọ wíwọ̀ nínú eré náà ni ó wúni lórí.

Lábẹ́lẹ̀, òdodo ọ̀rọ̀ ni ó ń bẹ nípa bí àwọn olóṣèlú Nàìjíríà ṣe ń hùwà. Ó dúró gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fún wọn. Ẹ̀yin Lápitẹ́ ò dára. Níparí, ọ̀kánjúwà ni ó fi òpin sí ìgbésí ayé rẹ̀.Kò mọ̀ pé ibi tí a bá pè ní orí, a kì í fibẹ̀ tẹlẹ̀”.

Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé kò tí ì pé oṣù mẹ́fà tí arábìnrin Macaulay bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá pẹ̀lú Ìyá Yorùbá tí àkọsílẹ̀ wọn sì wúni lórí báyìí.

Arábìnrin Ronke Macaulay pẹ̀lú olùkọ́ wọn Ìyá Yorùbá

Ẹ kú iṣẹ́ takuntakun náà arábìnrin Ronke Macaulay!

2 thoughts on “ÀGBÉYẸ̀WÒ FÍÌMÙ “ṢAWOROIDẸ” TÍ Ọ̀GBẸ́NI TUNDE KELANI GBÉ JÁDE

  1. Ẹ kú iṣẹ́ gidigan o! Kí èèyàn kọ àgbéyẹ̀wò fíìmù kìí ṣe nǹkan tó rọrùn. Èmi gan fún ra mi tí ń sọ wípé ọjọ́ kan, màá bẹ̀rẹ̀ sí kọ àgbéyẹ̀wò àwọn eré e Nollywood sí orí Íńtánẹ́ẹ̀tì!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *