Uncategorized

The Yorùbá Name “ÀÌNÁ”

Àìná jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn orúkọ àmútọ̀runwá Yorùbá tí wọ́n máa ń sọ ọmọ tí ó bá gbé ìwọ́ rẹ kọ́rùn nígbà tí wọ́n bá bí i. Orúkọ náà túmọ̀ sí “Ẹni tí a ò gbọdọ̀ nà”.
Iṣẹ́ kan náà ni orúkọ Òjó àti Àìná ń ṣe, ọmọkùnrin nìkan ni a lè sọ ní Òjó. Ṣùgbọ́n àtọkùnrin àtobìnrin ni a lè sọ ní Àìná.
Àṣà sísọ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ní Àìná gbalẹ̀ púpọ̀ láàárín àwọn Ìjẹ̀bú, èyí ń ṣe àlàyé òwe tí ó sọ pé “Ìjẹ̀bú kì í jẹ́ Òjó”.
Ọmọ ọlọ́lá ni a ka Àìná sí nítorí pé ìwọ́ tí ó gbé kọ́rùn wáyé ń ṣe àpẹẹrẹ ìlẹ̀kẹ̀ oyè.

A gbọ́ pé àwọn Àìná máa ń ní ìgboyà bákan náà ni wọ́n máa ń tètè bínú, epo pupa sì ni ẹ̀rọ̀ ìbínú wọn. Tí ènìyàn bá ti ta epo sílẹ̀ ní ìtòsí ibi tí wọ́n ti ń bínú tàbí tí Àìná náà fúnra rẹ bá mú epo, ara rẹ̀ á balẹ̀. Àwọn Àìná á sì máa fẹ́ràn epo pupa.

Oríkì Àìná ni:
Àìná Òrosùn roolo
Ó ní gúdá ibi
A jí náwó ara
Àìná kẹ̀kẹ́ ló gùn
Ẹni a bẹ̀ bẹ̀ bẹ̀ kó tó ṣẹ̀ṣọ́
Tibí ò jẹ́ kó rọ́kọ̀ ní
Ò lépo ní kóló
Ò ládìyẹ lába
A jí bọ́ba rẹ́
A jí jẹran tó tóbi
Egungun gbàǹgbà níṣasùn.

The Yorùbá name “Àìná” (À ìí nà án) which literally translates to “one who should not be beaten” is a predestined name (Orúkọ àmútọ̀runwá given to a child born with the umbilical cord twined round its neck. While Òjó is strictly for a male children, Àìná can be for both genders.
The name Àìná is considered unisex more amongst the Ìjẹ̀bú Clan as they don’t bear Òjó amongst the Ìjẹ̀bú. This confirms the proverb that says “No Ìjẹ̀bú bears Òjó”.
Àìná is believed to be a child of royalty as the umbilical cord on the neck at birth symbolizes bead.
Àìná is said to be a bold and strong child who gets easily angered and calmed easily after palm oil is being poured on the floor close to where he/she is. Or after he/she drinks palm oil directly.
Ainas are also said to be lovers of palm oil.

Àìná can be eulogized as:
Àìná Òrosùn roolo
Ó ní gúdá ibi
A jí náwó ara
Àìná kẹ̀kẹ́ ló gùn
Ẹni a bẹ̀ bẹ̀ bẹ̀ kó tó ṣẹ̀ṣọ́
Tibí ò jẹ́ kó rọ́kọ̀ ní
Ò lépo ní kóló
Ò ládìyẹ lába
A jí bọ́ba rẹ́
A jí jẹran tó tóbi
Egungun gbàǹgbà níṣasùn.

One thought on “The Yorùbá Name “ÀÌNÁ”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *