Àṣà (Culture)

Iṣẹ́ Ṣíṣe ní Ilẹ̀ Yorùbá

“Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ ilẹ̀ wá”. – A Yorùbá song


Ní ayé àtijó, kò sí àwọn iṣẹ́ àwòṣe (apprenticeship) lọ títí. Àwọn iṣẹ́ tí ó wọ́pọ̀, tí wọ́n sì ṣe pàtàkì lásìkò náà ni àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀ǹbáyé Yorùbá. Èyí ni àwọn iṣẹ́ tí ìdílé kọ̀ọ̀kan ń ṣe, tí àwọn ọmọ sì máa ń jogúnbá lọ́wọ́ àwọn òbí wọn.
Ẹni tí wọ́n bá bí sínú àwọn ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe irú àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí, irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe. Lára àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀ǹbáyé tí à ń sọ̀rọ̀ nípa ni:
Ìkòkò Mímọ
Epo Ṣíṣe
Àdí Ṣíṣe
Iṣẹ́ Àgbẹ̀
Iṣẹ́ Ọdẹ
Akọ̀pẹ (Emu dídá)
Aró Dídá
Aṣọ Híhun
Igbá Fífín
Iṣẹ́ Ọnà
Iṣẹ́ Àyàn
Orin Kíkọ
Àgbẹ̀dẹ

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *